Matthew 11:21-23

21Ó wí pé, “Ègbé ni fún ìwọ Koraṣini, ègbé ni fún ìwọ Betisaida! Ìbá ṣe pé a ti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu tí a ṣe nínú yín ní a ṣe ni Tire àti Sidoni, àwọn ènìyàn wọn ìbá ti ronúpìwàdà ti pẹ́ nínú aṣọ ọ̀fọ̀ àti eérú. 22Ṣùgbọ́n mo wí fún yín, yóò sàn fún Tire àti Sidoni ní ọjọ́ ìdájọ́ jù fún yín. 23Àti ìwọ Kapernaumu, a ó ha gbé ọ ga sókè ọ̀run? Rárá, a ó rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ sí ipò òkú. Nítorí, ìbá ṣe pé a ti ṣe iṣẹ́ ìyanu tí a ṣe nínú rẹ ní Sodomu, òun ìbá wà títí di òní.
Copyright information for YorBMYO